1 Ìran tí wòlíì Hábákúkù rí.
2 Olúwa, emì yóò ti ké pẹ́ tó fún ìrànlọ́wọ́,Ṣùgbọ́n ti ìwọ kò ni fetí sí mi?Tàbí kígbe sí ọ ní ti, “Ìwà ipá!”ṣùgbọ́n tí ìwọ kò sì gbàlà?
3 Èéṣe tí ìwọ fi mú mi rí àìṣedéédéÈéṣe tí ìwọ sì fààyè gba ìwà ìkà?Ìparun àti ìwà ipá wà ní iwájú mi;ìjà ń bẹ, ìkọlù sì wà pẹ̀lú.
4 Nítorí náà, òfin di ohun àìkàsí,ìdájọ́ òdodo kò sì borí.Àwọn ẹni búburú yí àwọn olódodo ká,Nítorí náà ni ìdájọ́ òdodo ṣe yí padà
5 “Ẹ wo ìnú àwọn aláìkọlà, ki ẹ sí wòye,Kí ìyàlẹnu kí o sí ṣe yin gidigidiNítorí tí èmi yóò ṣe ohun kan ni òwúrọ̀ ọjọ́ ọ yíntí ẹ̀yin kì yóò sì gbàgbọ́bí o tilẹ̀ jẹ́ pé a sọ fún un yin.
6 Nítorí pé, èmi yóò gbé àwọn ara Bábílónì dìde,àwọn aláìláàánú àti onínú fùfù ènìyàntí ó rin gbogbo ilẹ̀ ayé jáláti fi agbára gbà àwọn ibùgbé tí kì í ṣe ti wọn.
7 Wọn jẹ́ ènìyàn ti a bẹ̀rù, tí a sì páyà,ìdájọ́ wọn, àti ọláńlá wọn,Yóò máa ti inú wọn jáde.