1 Èmi yóò dúró lórí ibùṣọ́ mi láti máa wòyeÈmi yóò sì gbé ara mi ka orí alóreÈmi yóò si ṣọ́ láti gbọ́ ohun tí yóò sọ fún nuàti èsì ti èmi yóò fún ẹ̀sùn yìí nígbà tó bá ń bá mi wí;
2 Nígbà náà ni Olúwa dáhun pé:“Kọ ìṣípayá náa sílẹ̀kí o sí han ketekete lórí wàláàkí ẹni tí ń kà á, lè máa sáré.
3 Nítorí ìṣípayá náà jẹ́ tí ìgbà kan tí a múra sílẹ̀ dè;yóò máa yára sí ìgbẹ̀yinkí yóò sí sọ èkébí o tilẹ̀ lọ́ra, dúró dè é;nítorí, dájúdájú, yóò dé, kí yóò sí pẹ́”
4 “Kíyèsí, ọkàn rẹ tí ó gbéga;Ìfẹ́ rẹ̀ kò dúró ṣinṣin nínú rẹ̀,ṣùgbọ́n olododo yóò wa nípa ìgbàgbọ́ rẹ̀.