11 Nítorí tí òkúta yóò kígbe jáde láti inú ògiri wá,àti ìtí igi láti inú igi rírẹ́ wá yóò sì dá a lóhùn.
12 “Ègbé ni fún ẹni tí ó fi ẹ̀jẹ̀ kọ́ ìlú,tí o sì fi àìṣedéédéé tẹ ìlú ńlá dó?
13 Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun kò ha ti ṣètò rẹ̀ pélàálàá àwọn ènìyàn jẹ́ epo fún inákí àwọn orílẹ̀-èdè náà sì máa ṣe wàhálà fún aṣán?
14 Nítorí tí ayé yóò kún fún ìmọ̀ ògo Olúwa,bí omi ṣe bo òkun.
15 “Ègbé ni fún ẹni tí ó fi ohun mímu fún aládùúgbò rẹ̀,tí ó sì fí ọtí-lílé rẹ̀ fún un, tí o sì jẹ́ kó mu àmupara,kí ìwọ kí ó ba lè wo ìhòòhò wọn
16 Ìtì jú yóò bò ọ́ dípò ògo, ìwọ náà mu pẹ̀lúkí ìhòòhò rẹ kí ó lè hàn,aago ọwọ́ ọ̀tún Olúwa, yóò yípadà sí ọ,ìtìjú yóò sì bo ògo rẹ.
17 Nítorí ìwà-ipá tí ó tí hù sí Lébánónì yóò bò ọ́,àti ìparun àwọn ẹranko yóò dẹ́rùbà ọ́.Nítorí ìwọ tí ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀;ìwọ tí pa ilẹ̀ náà àti ìlú ńlá run àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.