13 Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun kò ha ti ṣètò rẹ̀ pélàálàá àwọn ènìyàn jẹ́ epo fún inákí àwọn orílẹ̀-èdè náà sì máa ṣe wàhálà fún aṣán?
14 Nítorí tí ayé yóò kún fún ìmọ̀ ògo Olúwa,bí omi ṣe bo òkun.
15 “Ègbé ni fún ẹni tí ó fi ohun mímu fún aládùúgbò rẹ̀,tí ó sì fí ọtí-lílé rẹ̀ fún un, tí o sì jẹ́ kó mu àmupara,kí ìwọ kí ó ba lè wo ìhòòhò wọn
16 Ìtì jú yóò bò ọ́ dípò ògo, ìwọ náà mu pẹ̀lúkí ìhòòhò rẹ kí ó lè hàn,aago ọwọ́ ọ̀tún Olúwa, yóò yípadà sí ọ,ìtìjú yóò sì bo ògo rẹ.
17 Nítorí ìwà-ipá tí ó tí hù sí Lébánónì yóò bò ọ́,àti ìparun àwọn ẹranko yóò dẹ́rùbà ọ́.Nítorí ìwọ tí ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀;ìwọ tí pa ilẹ̀ náà àti ìlú ńlá run àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.
18 “Èrè kí ni òrìṣà ni, tí oníṣọ̀nà rẹ̀ fi gbẹ́ ẹ,ère dídá àti olùkọ́ èké?Nítorí ti ẹni ti ó dá a gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé ohun tí ó fúnrarẹ̀ dá;ó sì mọ ère tí kò le fọhùn.
19 Ègbé ni fún ẹni ti ń sọ fún igi pé, ‘Wá ṣayé?’Fún òkúta tí kò lè fọhùn pé, ‘Dìde’Ǹjẹ́ òun lè tọ́ ni sí ọ̀nà?Góòlù àti sílífa ni a fi bò ó yíká;kò sì sí èémí kan nínú rẹ