Hábákúkù 2:4-10 BMY

4 “Kíyèsí, ọkàn rẹ tí ó gbéga;Ìfẹ́ rẹ̀ kò dúró ṣinṣin nínú rẹ̀,ṣùgbọ́n olododo yóò wa nípa ìgbàgbọ́ rẹ̀.

5 Bẹ́ẹ̀ ni pẹ̀lú, nítorí tí ọtí-wáìnì ni ẹ̀tàn,agbéraga ènìyàn òun, kò sì ní sinmiẹni tí ó sọ ìfá rẹ di gbígbòòrò bí ipò-òkú,ó sì dàbí ikú, a kò sì le tẹ́ ẹ lọ́rùn,ó kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ sí ọ̀dọ̀ó sì gba gbogbo ènìyàn jọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀.

6 “Gbogbo àwọn wọ̀nyí kì yóò máa pa òwe sí i tí wọn yóò sì máa kọ orin òwe sí i wí pé,“ ‘Ègbé ni fún ẹni tí ń mu ohun tí kì í ṣe tirẹ̀ pọ̀ sí i!Tí ó sì ṣọ ara rẹ̀ di ọlọ́rọ̀ nípaṣẹ̀ ìlọ́nilọ́wọ́ gbà!Eléyìí yóò ha ti pẹ́ tó?’

7 Ǹjẹ́ ẹni ti ó yọ ọ́ lẹ́nu, kí yóò ha dìde lójijì?Àti àwọn tí ó wàhálà rẹ kì yóò ha jí ni bi?Nígbà náà ni ìwọ yóò wa dí ìkógun fún wọn.

8 Nítorí ìwọ tí ko orílẹ̀-èdè púpọ̀,àwọn ènìyàn tó kù yóò sì kó ọnítorí ìwọ tí ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀; nítorí ẹ̀jẹ̀Ìwọ tí pa ilẹ̀ àti ìlú ńlá runàti gbogbo ènìyàn to ń gbé inú rẹ̀.

9 “Ègbé ni fún ẹni tí ń jẹ èrè ìjẹkújẹ sí ilé rẹ̀,tí o sí gbé ìtẹ́ rẹ̀ lórí ibi gíga,kí a ba le gbà á sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ibi!

10 Ìwọ ti gbìmọ̀ ìtìjú sí ilé rẹnípa kíké ènìyàn púpọ̀ kúrò;ìwọ sì ti pàdánù ẹ̀mi rẹ