1 Àdúrà wòlíì Hábákúkù gẹ́gẹ́ bí sígónótì.
2 Olúwa mo tí gbọ́ ohùn rẹ;ẹrú sì ba mi fún iṣẹ́ rẹ Olúwaṣọ wọn di ọ̀tún ní ọjọ́ ti wa,ní àkókò tiwa, jẹ́ kó di mímọ̀;ni ìbínú, rántí àánú.
3 Ọlọ́run yóò wa láti Témánì,Ibi mímọ́ jùlọ láti Òkè Páránìògo rẹ̀ sí bo àwọn ọ̀run,Ilé ayé sì kún fún ìyìn rẹ
4 Dídán rẹ ṣí dàbí ìmọ́lẹ̀;Ìmọ́lẹ̀ kọ-ṣàn-án láti ọwọ́ rẹ wá,níbi tí wọn fi agbára rẹ̀ pamọ́ sí.
5 Àjàkálẹ̀ àrùn ń lọ ni iwájú rẹ;ìyọnu ṣí ń tọ ẹsẹ̀ rẹ lọ.
6 Ó dúró, ó sì mi ayé;ó wò, ó sì mú àwọn orílẹ̀-èdè wárìrìa sì tú àwọn òkè-ńlá ayérayé ká,àwọn òkè kéékèèkéé ayérayé sì tẹríba:ọ̀nà rẹ ayérayé ni.
7 Mo rí àgọ́ Kúṣánì nínú ìpọ́njúàti àwọn ibùgbé Mídíanì nínú ìrora.