Míkà 1:1-7 BMY

1 Ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Míkà ará Mórésétì wá ní àkókò ìjọba Játamù, Áhásì, àti Heṣekáyà, àwọn ọba Júdà nìwọ̀nyí, ìran tí ó rí nípa Samaríà àti Jérúsálẹ́mù.

2 Ẹ gbọ́, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn,fétísílẹ̀, ìwọ ayé àti gbogbo ohun tó wà níbẹ̀,kí Olúwa alààyè lè ṣe ẹlẹ́rìí sí yín, Olúwa láti inú tẹ́ḿpìlì mímọ́ rẹ̀ wá.

3 Wò ó! Olúwa ń bọ̀ wá láti ibùgbé rẹ̀;yóò sọ̀kalẹ̀, yóò sì tẹ ibi gíga ayé mọ́lẹ̀.

4 Àwọn òkè ńlá yóò sí yọ́ lábẹ́ rẹ̀,àwọn àfonífojì yóò sì pín yà,bí idà níwájú iná,bí omi tí ó ń ṣàn lọ ni ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́.

5 Nítorí ìré-òfin-kọjá Jákọ́bù ni gbogbo èyí,àti nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ilé Ísírẹ́lì.Kí ni ìré-òfin-kọjá Jákọ́bù?Ǹjẹ́ Samaríà ha kọ?Kí ni àwọn ibi gíga Júdà?Ǹjẹ́ Jérúsálẹ́mù ha kọ?

6 “Nítorí náà, èmi yóò ṣe Samaríà bí òkítì lórí pápá,bí ibi ti à ń lò fún gbíngbin àjàrà.Èmi yóò gbá àwọn òkúta rẹ̀ dànù sínú àfonífojì.Èmi yóò sí tú ìpilẹ̀sẹ̀ rẹ̀ palẹ̀.

7 Gbogbo àwọn ère fífín rẹ̀ ni a ó fọ́ sí wẹ́wẹ́gbogbo àwọn ẹ̀bùn tẹ́ḿpìlì rẹ̀ ni a ó fi iná sun:Èmi yóò sí pa gbogbo àwọn òrìṣà rẹ̀ run.Nítorí tí ó ti kó àwọn ẹ̀bùn rẹ̀ jọ láti inú owó èrè panṣágà,gẹ́gẹ́ bí owó èrè panṣágà, wọn yóò sì tún padà sí owó iṣẹ́ panṣágà.”