Míkà 1:6-12 BMY

6 “Nítorí náà, èmi yóò ṣe Samaríà bí òkítì lórí pápá,bí ibi ti à ń lò fún gbíngbin àjàrà.Èmi yóò gbá àwọn òkúta rẹ̀ dànù sínú àfonífojì.Èmi yóò sí tú ìpilẹ̀sẹ̀ rẹ̀ palẹ̀.

7 Gbogbo àwọn ère fífín rẹ̀ ni a ó fọ́ sí wẹ́wẹ́gbogbo àwọn ẹ̀bùn tẹ́ḿpìlì rẹ̀ ni a ó fi iná sun:Èmi yóò sí pa gbogbo àwọn òrìṣà rẹ̀ run.Nítorí tí ó ti kó àwọn ẹ̀bùn rẹ̀ jọ láti inú owó èrè panṣágà,gẹ́gẹ́ bí owó èrè panṣágà, wọn yóò sì tún padà sí owó iṣẹ́ panṣágà.”

8 Nítorí èyí, èmi yóò sì sunkún,èmi yóò sì pohùnréré ẹkún:èmi yóò máa lọ ní ẹsẹ̀ lásán àti ní ihòòhòÈmi yóò ké bí akátá,èmi yóò sì máa dárò bí àwọn ọmọ ògòǹgò.

9 Nítorí tí ọgbẹ́ rẹ̀ jẹ́ aláìlewòtán;ó sì ti wá sí Júdà.Ó sì ti dé ẹnu bodè àwọn ènìyàn mi,àní sí Jérúsálẹ́mù.

10 Ẹ má ṣe sọ ní Gátìẹ má ṣe sunkún rárá.Ní ilẹ̀ Bẹti-ófíràmo yí ara mi nínú eruku.

11 Ẹ kọjá lọ ni ìhòòhò àti ni ìtìjú,ìwọ tí ó ń gbé ni Sáfírì.Àwọn tí ó ń gbé ni Sáánánìkì yóò sì jáde wá.Bétésélì wà nínú ọ̀fọ̀;A ó sì gba ààbò rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ yin.

12 Nítorí àwọn tí ó ń gbé ni Márátì ń retí ire,Ṣùgbọ́n ibi sọ̀kalẹ̀ ti ọ̀dọ̀ Olúwa wá sí ẹnu bodè Jérúsálẹ́mù.