1 Ègbé ni fún àwọn tí ń gbérò àìṣedéédéétí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ ibi lórí ibùsùn wọn!Nígbà tí ojúmọ́ bá mọ́, wọn yóò gbé e jádenítorí ó wà ní agbára wọn láti se é.
2 Wọ́n sì ń ṣe ojúkòkòrò oko, wọ́n sì fi agbára wọn gbà wọ́n,àti àwọn ilé, wọ́n sì gbà wọ́n.Wọ́n sì ni ènìyàn àti ilẹ̀ rẹ̀ láraàni ènìyàn àti ohun ìní rẹ̀.
3 Nítorí náà, Olúwa wí pé:“Èmi ń gbérò ibi sí àwọn ìdílé wọ̀nyí,nínú èyí tí wọn kì yóò le è gba ara wọn là.Ìwọ kì yóò sì lè máa rìn ní ìgbéraga mọ́,nítorí yóò jẹ́ àkókò ibi.
4 Ní ọjọ́ náà ni ẹnìkan yóò fi ọ́ ṣe ẹlẹ́yà;wọn yóò sì pohùn réré ẹkún kíkorò pé:‘Ní kíkó a ti kó wọn tán; Olúwa ti pín ohun ìní àwọn ènìyàn mi;Ó ti mú un kúrò lọ́dọ̀ mi!Ó fi oko wa lé àwọn ọlọ̀tẹ̀ lọ́wọ́.’ ”
5 Nítorí náà, ìwọ kò ní ní ẹnìkan kan nínú ìjọ Olúwa,tí yóò pín ilẹ̀ nípa ìbò.
6 “Ẹ má ṣe ṣọ̀tẹ̀lẹ̀,” ni àwọn Wòlíì wọn wí.“Ẹ má ṣe ṣọtẹ́lẹ̀ nípa nǹkan wọ̀nyí;kí ìtìjú má ṣe le bá wa”
7 Ṣé kí á sọ ọ́, ìwọ ilé Jákọ́bù:“Ǹjẹ́ ẹ̀mí Olúwa ha ń bínú bí?Ǹjẹ́ iṣẹ́ rẹ ha nì wọ̀nyí?”“Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ mi kò ha ń ṣe rerefún ẹni tí ń rìn déédé bí?