3 Nítorí náà, Olúwa wí pé:“Èmi ń gbérò ibi sí àwọn ìdílé wọ̀nyí,nínú èyí tí wọn kì yóò le è gba ara wọn là.Ìwọ kì yóò sì lè máa rìn ní ìgbéraga mọ́,nítorí yóò jẹ́ àkókò ibi.
4 Ní ọjọ́ náà ni ẹnìkan yóò fi ọ́ ṣe ẹlẹ́yà;wọn yóò sì pohùn réré ẹkún kíkorò pé:‘Ní kíkó a ti kó wọn tán; Olúwa ti pín ohun ìní àwọn ènìyàn mi;Ó ti mú un kúrò lọ́dọ̀ mi!Ó fi oko wa lé àwọn ọlọ̀tẹ̀ lọ́wọ́.’ ”
5 Nítorí náà, ìwọ kò ní ní ẹnìkan kan nínú ìjọ Olúwa,tí yóò pín ilẹ̀ nípa ìbò.
6 “Ẹ má ṣe ṣọ̀tẹ̀lẹ̀,” ni àwọn Wòlíì wọn wí.“Ẹ má ṣe ṣọtẹ́lẹ̀ nípa nǹkan wọ̀nyí;kí ìtìjú má ṣe le bá wa”
7 Ṣé kí á sọ ọ́, ìwọ ilé Jákọ́bù:“Ǹjẹ́ ẹ̀mí Olúwa ha ń bínú bí?Ǹjẹ́ iṣẹ́ rẹ ha nì wọ̀nyí?”“Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ mi kò ha ń ṣe rerefún ẹni tí ń rìn déédé bí?
8 Láìpẹ́ àwọn ènìyàn mi dìdebí ọ̀tá sí mi.Ìwọ bọ́ aṣọ ọlọ́rọ̀kúrò lára àwọn tí ń kọjá lọ ní àìléwu,bí àwọn ẹni tí ó padà bọ̀ láti ojú ogun.
9 Ẹ̀yin sì lé obìnrin àwọn ènìyàn mikúrò nínú ilé ayọ̀ wọn,ẹ̀yin sì ti gba ògo mi,kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ wọn láéláé.