1 Àwọn apanirun ti dìde sí ọ, ìwọ Nínéfèpa ilé-ìsọ́ mọ́,ṣọ́ ọ̀nà náàdi àmùrè, ẹ̀gbẹ́ rẹ kí ó le,múra gírí.
2 Olúwa yóò mú ọláńlá Jákọ́bù padà sípògẹ́gẹ́ bí ọláńlá Ísírẹ́lìbí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn apanirun ti pa ibẹ̀ run,tí wọ́n sì ti run àwọn àjàrà wọn.
3 Asà àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì di pupa;àwọn ológun wọn sì wọ aṣọ òdòdó.Idẹ tí ó wà lórí kẹ̀kẹ́ ogun ń kọ mọ̀nàmọ̀nàní ọjọ́ tí a bá pèsè wọn sílẹ̀ tán;igi fìrì ni a ó sì mì tìtì.
4 Àwọn kẹ̀kẹ́ ogun yóò ya bo àwọn pópónà,wọn yóò sì máa sáré síwá àti sẹ́yìn ní àárin ìgboro.Wọn sì dàbí ètúfú iná;tí ó sì kọ bí i mọ̀nàmọ́ná.