4 Àwọn kẹ̀kẹ́ ogun yóò ya bo àwọn pópónà,wọn yóò sì máa sáré síwá àti sẹ́yìn ní àárin ìgboro.Wọn sì dàbí ètúfú iná;tí ó sì kọ bí i mọ̀nàmọ́ná.
5 Òun yóò ṣe àṣàrò àwọn ọlọ́lá rẹ̀;ṣíbẹ̀ wọ́n ń kọsẹ̀ ní ojú ọ̀nà wọn;wọn sá lọ sí ibi odi rẹ̀,a ó sì pèsè ààbò rẹ̀.
6 A ó sí ìlẹ̀kùn àwọn odò wọ̀n-ọn-nì sílẹ̀,a ó sì mú ààfin náà di yíyọ́.
7 A pa á láṣẹ pé ìlú náà Èyí tí a ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ni kí a kó ní ìgbèkùn lọ.A ó sì mú un gòkè wáàti awọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ yóò ti ohùn bí ti oriri, ṣe amọ̀nà rẹ̀,wọn a sì máa lu àyà wọn.
8 Nínéfè dàbí adágún omi,tí omi wọn sì ń gbẹ́ ẹ lọ.“Dúró! Dúró!” ni wọ́n ó máa kígbe,ṣùgbọ́n ẹnikankan kì yóò wo ẹ̀yìn.
9 “Ẹ kó ìkógun fàdákà!Ẹ kó ìkógun wúrà!Ìṣúra wọn ti kò lópin náà,àti ọrọ̀ kúrò nínú gbogbo ohun èlò ti a fẹ́!”
10 Òun ti ṣòfò, ó si di asán, ó sì di ahoro:ọkàn pami, éekún ń lu ara wọn,ìrora púpọ̀ sì wà nínú gbogbo ẹgbẹ́àti ojú gbogbo wọ́n sì rẹ̀wẹ̀sì.