5 Òun yóò ṣe àṣàrò àwọn ọlọ́lá rẹ̀;ṣíbẹ̀ wọ́n ń kọsẹ̀ ní ojú ọ̀nà wọn;wọn sá lọ sí ibi odi rẹ̀,a ó sì pèsè ààbò rẹ̀.
6 A ó sí ìlẹ̀kùn àwọn odò wọ̀n-ọn-nì sílẹ̀,a ó sì mú ààfin náà di yíyọ́.
7 A pa á láṣẹ pé ìlú náà Èyí tí a ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ni kí a kó ní ìgbèkùn lọ.A ó sì mú un gòkè wáàti awọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ yóò ti ohùn bí ti oriri, ṣe amọ̀nà rẹ̀,wọn a sì máa lu àyà wọn.
8 Nínéfè dàbí adágún omi,tí omi wọn sì ń gbẹ́ ẹ lọ.“Dúró! Dúró!” ni wọ́n ó máa kígbe,ṣùgbọ́n ẹnikankan kì yóò wo ẹ̀yìn.
9 “Ẹ kó ìkógun fàdákà!Ẹ kó ìkógun wúrà!Ìṣúra wọn ti kò lópin náà,àti ọrọ̀ kúrò nínú gbogbo ohun èlò ti a fẹ́!”
10 Òun ti ṣòfò, ó si di asán, ó sì di ahoro:ọkàn pami, éekún ń lu ara wọn,ìrora púpọ̀ sì wà nínú gbogbo ẹgbẹ́àti ojú gbogbo wọ́n sì rẹ̀wẹ̀sì.
11 Níbo ni ihò àwọn kìnnìún wààti ibi ìjẹun àwọn ọmọ kìnnìún,níbi tí kìnnìún, àní abo kìnnìún ti ń rìn,àti ọmọ kìnnìún, láìsí ohun ìbẹ̀rù