1 Ègbé ni fún ìlú ẹ̀jẹ̀ nì,gbogbo rẹ̀ kún fún èké,àti olè,ìja kò kúrò!
2 Ariwo pàṣán àti ariwokíkùn kẹ̀kẹ́ ogunàti jíjó ẹṣin àti gbígbọ̀nkẹ̀kẹ́ ogun jìgìjìgì!
3 Ológun orí ẹṣin ń fi ìgbónáraju ìdà wọn mọ̀nàmọ̀nàọ̀kọ̀ rẹ̀ ti ń dán yanran sí òkè!Ọ̀pọ̀lọpọ̀ si ní àwọn ẹni tí a pa,àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ òkú;òkú kò si ni òpin;àwọn ènìyàn sì ń kọsẹ̀ lára àwọn òkú.
4 Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn panṣágààgbèrè tí ó rójú rere gbà,Iyá àjẹ́ tí ó sọ́ àwọn orilẹ̀-èdè di ẹrúnipa àgbèrè rẹ̀àti àwọn ìdílé nipa ìṣe àjẹ́ rẹ̀.
5 “Èmi dojú kọ ọ́,” ni Olúwa awọn ọmọ ogun wí.“Èmi ó si ká aṣọ ìtẹ́lẹ̀dì rẹ ní ojú rẹ,Èmi yóò sì fi ìhòòhò rẹ̀ han àwọn orílẹ̀-èdèàti ìtìjú rẹ̀ han àwọn ilẹ̀ ọba.