9 Etiópíà àti Éjíbítì ni agbára rẹ, kò sí ní òpin;Pútì àti Líbíà ni àwọn olùgbèjà rẹ̀.
10 Ṣíbẹ̀ ṣíbẹ̀ a kó o ní ìgbèkùno sì lọ sí oko ẹrú.Àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ rẹ̀ ni a ó fọ́ mọ́lẹ̀ní orí ìta gbogbo ìgboro.Wọ́n sì di ìbò nítorí àwọn ọlọ́lá rẹ̀ ọkùnrin,gbogbo àwọn ọlọ́lá rẹ ni a sì fi ẹ̀wọ̀n dè
11 Ìwọ pẹ̀lú yóò sì mu àmupara;a ó si fi ọ́ pamọ́ìwọ pẹ̀lú yóò máa ṣe àfẹ́rí ààbò nítorí ti ọ̀tá náà.
12 Gbogbo ilé-ìṣọ́ agbára rẹ yóò dàbí igi ọ̀pọ̀tọ́pẹ̀lú àkọ́pọ́n èso wọn;Nígbà tí wọ́n bá ń gbọ̀n wọ́n,ọ̀pọ̀tọ́ yóò sì bọ́ sí ẹnu àwọn ọ̀jẹun.
13 Kíyè sí,Obínrin ni àwọn ènìyàn rẹ ní àárin!Ojú ibodè rẹ ní a ó sí sílẹ̀ gbagada,fún àwọn ọ̀tá rẹ̀;iná yóò jó ilẹ̀ rẹ
14 Ìwọ pọn omi de ìhámọ́,mú ile ìsọ́ rẹ lágbára sí iwọ inú amọ̀kí o sì tẹ erùpẹ̀,kí ó sì tún ibi tí a ti ń sun bíríkì-amọ̀ ṣe kí ó le.
15 Níbẹ̀ ni iná yóò ti jó ọ́ run;Idà yóò sì ké ọ kúrò,yóò sì jẹ ọ́ bí i kòkòrò,yóò sì sọ ara rẹ̀ di púpọ̀ bí i tata,àní, di púpọ̀ bí eṣú!