1 Ẹ̀yin pàápàá mọ̀, ará, pé ìbẹ̀wò wa sí i yín kì í ṣe ní asán.
2 Àwa tí jìyà, a sì fi àbùkù kàn wá ní ìlú Fílípì bí ẹ̀yin ti mọ̀, ṣùgbọ́n nípa ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run wa ní àwa fi ìgboyà sọ ìyìnrere fún un yín pẹ̀lú àtakò líle.
3 Nítorí ọ̀rọ̀ ìyànjú wa kì í se ti ẹ̀tàn, tàbí ti èrò àìmọ́, tàbí láti inú àrékérekè.
4 Ṣùgbọ́n bí a ti kà wá yẹ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, bí ẹni tí a fi ìyìnrere lé lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni àwa ń sọ, kì í se bí ẹni tí ń wu ènìyàn, bí kò se Ọlọ́run tí ń dán ọkàn wa wò.
5 A mọ̀ pé a kò lo ọ̀rọ̀ dídùn, tàbí ìbòjú ojúkòkòrò fún yín, Ọlọ́run ni ẹlẹ́rìí wa.
6 A kò bèèrè ìyìn lọ́dọ̀ yín tàbí fún ara wa. Gẹ́gẹ́ bí àpósítélì Kírísítì a ò bá ti di àjàgà fún un yín.
7 Ṣùgbọ́n àwa se pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ láàrin yín tí a sì se ìtọ́jú yín gẹ́gẹ́ bí ìyá ti ń tọ́jú àwọn ọmọ rẹ̀.