10 Nitòótọ́, ẹ ní ìfẹ́ fún àwọn arákùnrin tí ó wà káàkiri Makidóníà. Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀ àwa ń bẹ̀ yín, ará, pé kí ẹ̀yin kí ó máa tẹ̀síwájú nínú rẹ̀.
11 Ẹ jẹ́ kí èyí jẹ́ ìfẹ́ ọkàn yín láti gbé jẹ́ẹ́ àti láti mọ ti ara yín àti kí olúkúlùkù kọjú sí iṣẹ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí a ti wí fún yín.
12 Èyí yóò mú kí àwọn tí kì í se Kírísítẹ́nì gbẹ́kẹ̀lé yín àti láti bu ọlá fún yín pẹ̀lú. Bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ kò ní máa wo ojú ẹnikẹ́ni láti fún yín ni owó tí ẹ ó fi san gbèṣè.
13 Ẹ̀yin ará, àwa kò fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó jẹ́ òpè ní ti àwọn tí ó ti sùn, pé kí ẹ máa banújẹ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn yóòkù tí kò ní ìrètí.
14 A gbàgbọ́ pé, Jésù kú, ó sì tún jíǹde, pé Ọlọ́run yóò mú gbogbo àwọn tí ó ti sùn nínú rẹ̀ padà wá.
15 Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa, pé àwa tí ó wà láàyè, tí a sì kù lẹ́yìn de àtiwá Olúwa, bí ó ti wù kí ó rí, kì yóò ṣáájú àwọn tí ó sùn láti pàdé rẹ̀.
16 Nítorí pé, Olúwa fúnraarẹ́ yóò sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá, pẹ̀lú ariwo àṣẹ ńlá àti ohùn àwọn ańgẹ́lì ti àwọn ańgẹ́lì ti àwọn ti ìpè Ọlọ́run, àwọn òkú nínú Kírísítì yóò sì kọ́kọ́ jíǹde.