2 Nítorí pé, ẹyin mọ àṣẹ tí a pa fún yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa Jésù.
3 Nítorí ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé kí ẹ jẹ́ mímọ, kí ẹ sì yàgò kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àgbérè,
4 kí ẹnikọ̀ọ̀kan yín kọ́ láti sàkóso ara rẹ̀ ní ọ̀nà mímọ́ àti pẹ̀lú ọlá,
5 kì í ṣe ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn aláìkọlà, ẹni tí kò mọ Ọlọ́run;
6 àti pé nínú ọ̀rọ̀ yìí, kí ẹnikẹ́ni yín máa ṣe kùnà arákùnrin rẹ̀ nípa ohunkóhun. Olúwa yóò jẹ àwọn ènìyàn níyà fún gbogbo ẹ̀sẹ̀ wọn, gẹ́gẹ́ bí a ti ń sọ fún un yín tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀.
7 Nítorí Ọlọ́run kò pè wá sínú àìmọ́, bí kò ṣe sínúìgbé-ayé mímọ́.
8 Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó kọ òfin yìí, kì í se òfin ènìyàn ni ẹni náà kọ̀, bí kò ṣe òfin Ọlọ́run ẹni tí ó fi Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ fún ni.