1 Má ṣe bá àgbàlagbà ọkùnrin wí, ṣùgbọ́n kí ó máa gbà á níyànjú bíi bàbá; àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin bí arákùnrin.
2 Àwọn àgbàlagbà obìnrin bí ìyá; àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin bí arábìnrin nínú ìwà mímọ́.
3 Bọ̀wọ̀ fún àwọn opó ti í ṣe opó nítòótọ́.
4 Ṣùgbọ́n bí opó kan bá ni ọmọ tàbí ọmọ-ọmọ, jẹ́ kí wọn kọ́kọ́ kọ́ bí a ti ń ṣe ìtọ́jú ilé àwọn tìkárawọn, kí wọn sì san oore àwọn òbí wọn padà; nítorí pé èyí ni ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà níwájú Ọlọ́run.
5 Ǹjẹ́ ẹni ti í ṣe opó nítòótọ́, ti ó ṣe òun nìkan, a máa gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run, a sì máa dúró nínú ẹ̀bẹ̀ àti nínú àdúrà lọ́sàn àti lóru.
6 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá fi ara rẹ fún ayé-jíjẹ, ó kú nígbà tí ó wà láàyè.