7 Nǹkan wọ̀nyí ni kí wọn máa paláṣẹ, kí wọn lè wà láìlẹ́gàn
8 Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni kò bá pèsè fún àwọn tirẹ̀, pàápàá fún àwọn ara ilé rẹ̀, ó ti sẹ́ ìgbàgbọ́, ó burú ju aláìgbàgbọ́ lọ.
9 Kọ orúkọ ẹni tí kò bá dín ni ọgọ́ta ọdún sílẹ̀ bí opó, lẹ́yìn ti ó ti jẹ́ aya ọkọ kan.
10 Ẹni ti a jẹ́rì rẹ̀ fún iṣẹ́ rere; bí ẹni ti ó ti tọ́ ọmọ dàgbà, ti ó ń ṣe ìtọ́jú àlejò, tí ó sì ń wẹ ẹṣẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́, tí ó ti ran àwọn olupọ́njú lọ́wọ́, tí ó sì ń lépa iṣẹ́ rere gbogbo.
11 Ṣùgbọ́n kọ̀ (láti kọ orúkọ) àwọn opó tí kò dàgbà; nítorí pé nígbà ti wọn bá ti ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ lòdì sí Kírísítì, wọn á tún fẹ́ láti gbéyàwó.
12 Wọn á di ẹlẹ́bi, nítorí tí wọn ti kọ ìgbàgbọ́ wọn ìṣáájú sílẹ̀.
13 Àti pẹ̀lú wọn ń kọ́ láti ṣe ọ̀lẹ, láti máa kiri láti ile-dé-ilé, kì í ṣe ọ̀lẹ nìkan, ṣùgbọ́n onísọkúsọ àti olófòófó pẹ̀lú, wọn a máa sọ ohun tí kò yẹ.