14 Kí ìwọ pa àṣẹ wọ̀nyí mọ́ ní àìlábàwọ́n, ní àìlẹ́gàn, títí di ìfarahàn Olúwa wa Jésù Kírísítì.
15 Èyí ti yóò fi hàn ní ìgbà tirẹ̀, Ẹni tí í ṣe Olùbùkún àti Alágbára kan ṣoṣo náà, Ọba àwọn ọba, àti Olúwa àwọn Olúwa.
16 Ẹnìkan ṣoṣo tí ó ní àìkú, tí ń gbé inú ìmọ́lẹ̀ tí a kò lè súnmọ́, ẹni tí ènìyàn kan kò rí rí tí a kò sì lè rí: ẹni tí ọlá àti agbára títí láé ń ṣe tirẹ̀ (Àmín).
17 Kìlọ̀ fún àwọn tí ó lọ́rọ̀ ní ayé ìṣinṣinyìí kí wọn ma ṣe gbéraga, bẹ́ẹ̀ ni kí wọn má ṣe gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ àìdánilójú, bí kò se lé Ọlọ́run alààyè, tí ń fi ohun gbogbo fún wa lọ́pọ̀lọpọ̀ láti lò;
18 Kí wọn máa ṣoore, kí wọn máa pọ̀ ní iṣẹ́ rere, kí wọn múra láti pín fúnni, kí wọn ni ẹ̀mí ìbákẹ́dùn;
19 Kí wọn máa to ìṣúra ìpìlẹ̀ rere jọ fún ara wọn dé ìgbà tí ń bọ̀, kí wọn lè di ìyè tòótọ́ mú.
20 Tìmótíù, máa sọ ohun tí a fi sí ìtọ́jú rẹ, yà kúrò nínú ọ̀rọ̀ asán àti ìjiyàn ohun tí a ń fi èké pè ni ìmọ̀;