18 Kí wọn máa ṣoore, kí wọn máa pọ̀ ní iṣẹ́ rere, kí wọn múra láti pín fúnni, kí wọn ni ẹ̀mí ìbákẹ́dùn;
19 Kí wọn máa to ìṣúra ìpìlẹ̀ rere jọ fún ara wọn dé ìgbà tí ń bọ̀, kí wọn lè di ìyè tòótọ́ mú.
20 Tìmótíù, máa sọ ohun tí a fi sí ìtọ́jú rẹ, yà kúrò nínú ọ̀rọ̀ asán àti ìjiyàn ohun tí a ń fi èké pè ni ìmọ̀;
21 Èyí tí àwọn ẹlòmíràn jẹ́wọ́ rẹ̀ tí wọ́n sì sìnà ìgbàgbọ́.Kí oore-ọ̀fẹ́ wà pẹ̀lú rẹ. Àmín.