5 Àti ọ̀rọ̀ àyípo àwọn ènìyàn ọlọ́kàn èérí ti kò sí òtítọ́ nínú wọn, ti wọn ṣèbí ọ̀nà sí èrè ni ìwà-bí-Ọlọ́run; yẹra lọ́dọ̀ irú àwọn wọ̀nyí.
6 Ṣùgbọ́n ìwà-bí-Ọlọ́run pẹ̀lú ìtẹ́lọ́rùn èrè ńlá ni.
7 Nítorí a kò mu ohun kan wá sí ayé, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì lè mu ohunkóhun jáde lọ.
8 Bí a sì ni oúnjẹ àti aṣọ, ìwọ̀nyí yóò tẹ́ wa lọ́rùn.
9 Ṣùgbọ́n àwọn tí ń fẹ́ di ọlọ́rọ̀ a máa bọ́ sínú ìdánwò àti ìdẹkùn, àti sínú òmùgọ̀ ìfẹ́kùfẹ̀ẹ́ púpọ̀ tí í pa-ni-lára, irú èyí tí ó máa ń ri ènìyàn sínú ìparun àti ègbé.
10 Nítorí ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò ohun búburú gbogbo; èyí tí àwọn mìíràn ń lépa tí a sì mú wọn sìnà kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọ́n sì fi ọ̀pọ̀ ìbànújẹ́ gún ara wọn lọ́kọ̀.
11 Ṣùgbọ́n ìwọ ènìyàn Ọlọ́run, sá fún nǹkan wọ̀nyí; kí ó sì máa lépa òdodo, ìwà-bí-Ọlọ́run, ìgbàgbọ́, ìfẹ́ sùúrú, ìwà tútù.