8 Bí a sì ni oúnjẹ àti aṣọ, ìwọ̀nyí yóò tẹ́ wa lọ́rùn.
9 Ṣùgbọ́n àwọn tí ń fẹ́ di ọlọ́rọ̀ a máa bọ́ sínú ìdánwò àti ìdẹkùn, àti sínú òmùgọ̀ ìfẹ́kùfẹ̀ẹ́ púpọ̀ tí í pa-ni-lára, irú èyí tí ó máa ń ri ènìyàn sínú ìparun àti ègbé.
10 Nítorí ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò ohun búburú gbogbo; èyí tí àwọn mìíràn ń lépa tí a sì mú wọn sìnà kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọ́n sì fi ọ̀pọ̀ ìbànújẹ́ gún ara wọn lọ́kọ̀.
11 Ṣùgbọ́n ìwọ ènìyàn Ọlọ́run, sá fún nǹkan wọ̀nyí; kí ó sì máa lépa òdodo, ìwà-bí-Ọlọ́run, ìgbàgbọ́, ìfẹ́ sùúrú, ìwà tútù.
12 Má a ja ìjà rere ti ìgbàgbọ́, di ìyè àìnípẹ̀kun mú nínú èyí tí a pè ọ sí, ti ìwọ sì ṣe ìjẹ́wọ́ rere níwájú ẹlẹ́rìí púpọ̀.
13 Mo paṣẹ fún ọ níwájú Ọlọ́run, tí ń sọ ohun gbogbo di ààyè, àti níwájú Jésù Kírísítì, ẹni tí ó jẹ́rìí níwájú Pọ́ńtíù Pílátù,
14 Kí ìwọ pa àṣẹ wọ̀nyí mọ́ ní àìlábàwọ́n, ní àìlẹ́gàn, títí di ìfarahàn Olúwa wa Jésù Kírísítì.