1 Èmi Pọ́ọ̀lù, ẹni tí a fi sẹ́wọ̀n nítorí pé ó ń wàásù ìyìn rere Jésù Kírísítì àti Tímótíù arákùnrin wa.Sí Fílímónì ọ̀rẹ́ wa ọ̀wọ́n àti alábàáṣiṣẹ́ wa,
2 sí Áfíà arábìnrin wa, sí Ákípọ́sì ẹni tó jẹ́ jagunjagun fún àgbélébùú náà àti sí ìjọ àwọn Kírísítẹ́nì tí ó ń pàdé nínú ilé rẹ:
3 Oore-Ọ̀fẹ́ fún un yín àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa àti Jésù Kírísítì.
4 Èmi máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nígbà tí mo bá rántí rẹ nínú àdúrà mi,
5 nítorí mo ń gbọ́ nípa ìgbàgbọ́ rẹ nínú Jésù Olúwa àti nípa ìfẹ́ rẹ sí àwọn ènìyàn mímọ́.