18 Bí ó bá ti ṣe ọ́ ní ibi kan tàbí jẹ ọ́ ní gbésè ohun kan, kà á sí mi lọ́rùn.
19 Èmi Pọ́ọ̀lù, ni mo fi ọwọ́ ara mi kọ ìwé yìí; èmi yóò san án padà láì tilẹ̀ níí sọ nípa pé ìwọ pàápàá jẹ mi ní gbésè ara rẹ.
20 Èmi ń fẹ́, arákùnrin, pé kí èmi kí ó lè ni àǹfààní kan láti ọ̀dọ̀ rẹ nínú Olúwa; fi ayọ̀ rẹ kún ọkàn mi nínú Jésù.
21 Ìgbẹ́kẹ̀lé ti mo ní pé ìwọ yóò gbọ́ràn, ni mo fi kọ ìwé yìí ránsẹ́ sí ọ. Mo mọ̀ dájú pé ìwọ yóò se ju bí mo ti béèrè lọ.
22 Ó ku ohun kan: Ṣe ìtọ́jú ìyara àlejò rẹ sílẹ̀ fún mi, nítorí mo ní ìgbàgbọ́ pé a óò tú mi sílẹ̀ fún yín ní ìdáhùn sí àdúrà yín.
23 Ẹ́páfírà, òǹdè ẹlẹgbẹ́ mi nínú Kírísítì Jésù kí ọ.
24 Máàkù kí ọ pẹ̀lú Ańsíbákù, Dẹ́mà àti Lúùkù, àwọn alábàáṣiṣẹ́ mi.