1 Pọ́ọ̀lù àti Tìmótíù, àwọn ìránṣẹ́ Jésù Kírísítì,Sí gbogbo àwọn ènìyàn-mímọ́ nínú Kírísítì Jésù tí ó wà ní Fílípì, pẹ̀lú àwọn bíṣọ́ọ̀bù àti àwọn díákónì
2 Oore-ọ̀fẹ́ sí yín, àti àlàáfíà, láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa, àti Olúwa wa Jésù Kírísítì.
3 Mo ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run mi ní gbogbo ìgbà tí mo bá rántí yín:
4 Nínú gbogbo àdúrà mi fún-un yín, èmi ń fi ayọ̀ gbàdúrà,
5 nítorí ìdàpọ̀ yín nínú ìyìn rere láti ọjọ́ kìn-ín-ni wá títí di ìsinsinyìí.