15 Òtítọ́ ni pé àwọn ẹlòmíràn tilẹ̀ ń fi ìjà àti ìlara wàásù Kírísítì, ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmíràn sì ń fi inú rere ṣe é.
16 Àwọn ti ìkẹ́yìn n fi ìfẹ́ ṣe é, nítorí tí wọ́n mọ̀ pé a ó gbé mi dìde fún ìgbèjà ìyìn rere.
17 Ṣùgbọ́n àwọn ti ìṣáájú ẹ̀wẹ̀ ń fi ìlépa ara ẹni ń wàásù Kírísítì, kì í ṣe pẹ̀lú òótọ́ inú, wọn ń gbérò láti fi ìpọ́njú kún ìdè mi ni.
18 Ṣùgbọ́n ohun tí ó sa ṣe pàtàkì ni pé, bóyá a wàásù pẹ̀lú ètè tó dára tàbí èyí tí kò dára, a ṣsá ń wàásù Kírísítì. Èyí sì ni ayọ̀ mi.Bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò sì máa yọ̀;
19 Nítorí tí mo mọ̀ pé nípa àdúrà yín àti ìrànlọ́wọ́ tí Ẹ̀mí Jésù Kírísítì, ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí mi yóò padà já sí ìtúsílẹ̀ mi.
20 Ó jẹ́ ìfojúsọ́nà àti ìrètí mi pé ojú kì yóò tì mí nínú ohunkóhun, ṣùgbọ́n èmi ó ní ìgboyà nísinsìnyìí bí ti ìgbà gbogbo pé ní yíyè, tàbí ní kíkú, a ó gbé ga lára mi.
21 Nítorí, níti èmi, láti wa láàyè jẹ́ Kírísítì, láti kú jẹ́ èrè.