19 Nítorí tí mo mọ̀ pé nípa àdúrà yín àti ìrànlọ́wọ́ tí Ẹ̀mí Jésù Kírísítì, ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí mi yóò padà já sí ìtúsílẹ̀ mi.
20 Ó jẹ́ ìfojúsọ́nà àti ìrètí mi pé ojú kì yóò tì mí nínú ohunkóhun, ṣùgbọ́n èmi ó ní ìgboyà nísinsìnyìí bí ti ìgbà gbogbo pé ní yíyè, tàbí ní kíkú, a ó gbé ga lára mi.
21 Nítorí, níti èmi, láti wa láàyè jẹ́ Kírísítì, láti kú jẹ́ èrè.
22 Ṣùgbọ́n bí èmi bá sì wà láàyè nínú ara, èyí yóò jásí èrè fún iṣẹ́ mi. Síbẹ̀, kíni èmí yóò yàn? Èmi kò mọ̀?
23 Mo wà ní agbede méjì. Mo fẹ́ràn láti wà pẹ̀lú Kírísítì, èyí tí ó dára jùlọ.
24 Ṣùgbọ́n ó ṣe iyebíye fún yín kí èmi kí ó wà nínú ara.
25 Bí èyí sì ti dá mi lójú, mo mọ̀ pé èmi ó dúró, èmi ó sì máa wà pẹ̀lú yín fún ìtẹ̀síwájú àti ayọ̀ yín nínú ìgbàgbọ́,