5 nítorí ìdàpọ̀ yín nínú ìyìn rere láti ọjọ́ kìn-ín-ni wá títí di ìsinsinyìí.
6 Ohun kan yìí ṣáà dá mi lójú pé, ẹni tí ó ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rere nínú yín, yóò ṣe àṣepé rẹ̀ títí di ọjọ́ Jésù Kírísítì:
7 Gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́ fún mi láti ro èyí nípa gbogbo yín, nítorí tí mo fi yín sọ́kàn, bí mo tilẹ̀ wà nínú ìdè tàbí ìdáhùn ẹjọ́, àti ìfẹsẹmúlẹ̀ ìyìnrere, gbogbo yín jẹ́ alábàápín oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run pẹ̀lú mi.
8 Nítorí Ọlọ́run ni ẹlẹ́rìí mi, bí mo ti ń ṣàfẹ́rí yín gidigidi nínú ìfẹ́ Jésù Kírísítì.
9 Èyí sì ni àdúrà mi: pé kí ìfẹ́ yín lè máa pọ̀ síwájú àti ṣíwájú síi nínú ìfẹ́ àti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀,
10 kí ẹ̀yin kí ó lè dà ohun tí ó dára jùlọ yàtọ̀ mọ̀, kí ẹ sì jẹ́ mímọ́ àti aláìlábàwọ́n títí di ọjọ́ Kírísítì,
11 tí ẹ sì kún fún èso òdodo tí ó ti ọ́dọ̀ Jésù Kírísítì wá—fún ògo àti ìyìn Ọlọ́run.