Júdà 1:1-7 BMY

1 JÚDÀ, ìránṣẹ́ Jésù Kírísítì àti arákùnrin Jákọ́bù,Sí àwọn tí a pè, olùfẹ́ nínú Ọlọ́run Baba, tí a pamọ́ fún Jésù Kírísítì:

2 Kí àánú, àlàáfíà àti ìfẹ́ kí ó máa jẹ́ tiyín ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.

3 Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi tòótọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmí ní ìtara láti kọ̀wé sí i yín nípa ìgbàlà tí í ṣe ti gbogbo ènìyàn, n kò gbọdọ̀ má kọ̀wé sí yín, kí ń sì gbà yín ní ìyànjú láti máa jà fitafita fún ìgbàgbọ́, tí a ti fi lé àwọn ènìyàn mímọ́ lọ́wọ́ ní ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo.

4 Nítorí àwọn ènìyàn kan ń bẹ tí wọn ń yọ́ wọlé, àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run, tí ń yí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run wa padà sí wọ̀bìà, tí wọn sì ń ṣẹ́ Olúwa wa kansoso náà, àní Jésù Kírísítì Olúwa.

5 Nítòótọ́, ẹ ti mọ nǹkan wọ̀nyí ní ẹ̀ẹ̀kan rí, mo fẹ́ rán an yín létí pé, lẹ́yìn tí Olúwa ti gba àwọn kan là láti ilẹ̀ Éjíbítì wá, lẹ́yìn náà ni ó run àwọn tí kò gbàgbọ́.

6 Àti àwọn ańgẹ́lì tí kò tọ́jú ipò ọlá wọn, ṣùgbọ́n tí wọn fi ipò wọn sílẹ̀, àwọn tí ó pamọ́ sínú ẹ̀wọ̀n àìnípẹ̀kun ní ìṣàlẹ̀ òkùnkùn de ìdájọ ọjọ́ ńlá nì.

7 Àní bí Sódómù àti Gomorà, àti àwọn ìlú agbégbé wọn, ti fi ara wọn fún àgbérè ṣíṣe, tí wọ́n sì ń tẹ̀lé ará àjèjì lẹ́yìn, àwọn ni ó fi lélẹ̀ bí àpẹrẹ, àwọn tí ó ń jìyà iná àìnípẹ̀kun.