17 Ṣùgbọ́n ẹyin olùfẹ́, ẹ rántí àwọn ọ̀rọ tí a ti sọ ṣááju láti ọwọ́ àwọn Àpósítélì Olúwa wa Jésù Kírísítì.
18 Bí wọn ti wí fún yín pé, “Nígbà ìkẹyìn àwọn ẹlẹ́gàn yóò wà, tí wọn yóò máa rìn gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àìwà-bí-Ọlọ́run ti ara wọn.”
19 Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ni àwọn ẹni tí ń ya ara wọn sí ọ̀tọ̀, àwọn ẹni tí ara, tí wọn kò ni Ẹ̀mí.
20 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin, olùfẹ́, ti ẹ ń gbé ara yín ró lórí ìgbàgbọ́ yín tí ó mọ́ jùlọ, ti ẹ ń gbàdúrà nínú Ẹ̀mí Mímọ́.
21 Ẹ máa pa ara yín mọ́ nínú ìfẹ́ Ọlọ́run, bí ẹ̀yin ti ń rétí àánú Olúwa wa Jésù Kírísítì tí yóò mú yín dé ìyè àìnípẹ̀kun.
22 Ẹ máa yí àwọn tí ń ṣe iyèméjì lọ́kàn padà:
23 Ẹ máa gba àwọn ẹlòmíràn là, nípa fífà wọ́n yọ kúrò nínú iná; kí ẹ sì máa ṣàánú pẹ̀lú ìbẹ̀rù kí ẹ sì kórìíra ẹ̀wù tí ara ti sọ di èèrí.