22 Ẹ máa yí àwọn tí ń ṣe iyèméjì lọ́kàn padà:
23 Ẹ máa gba àwọn ẹlòmíràn là, nípa fífà wọ́n yọ kúrò nínú iná; kí ẹ sì máa ṣàánú pẹ̀lú ìbẹ̀rù kí ẹ sì kórìíra ẹ̀wù tí ara ti sọ di èèrí.
24 Ǹjẹ́ mo fi yín lé ẹni tí o lè pa yín mọ́ kúrò nínú ìkọsẹ̀, tí o sì lè mú yín wá ṣíwájú ògo rẹ̀ láilábùkù pẹ̀lú ayọ̀ ńlá lọ́wọ́—
25 tí Ọlọ́run ọlọ́gbọn níkan ṣoṣo, Olùgbàlà wa, ní ògo àti ọlá ńlá, ìjọba àti agbára, nísinsìn yìí àti títí láéláé! Àmín.