Júdà 1:3-9 BMY

3 Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi tòótọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmí ní ìtara láti kọ̀wé sí i yín nípa ìgbàlà tí í ṣe ti gbogbo ènìyàn, n kò gbọdọ̀ má kọ̀wé sí yín, kí ń sì gbà yín ní ìyànjú láti máa jà fitafita fún ìgbàgbọ́, tí a ti fi lé àwọn ènìyàn mímọ́ lọ́wọ́ ní ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo.

4 Nítorí àwọn ènìyàn kan ń bẹ tí wọn ń yọ́ wọlé, àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run, tí ń yí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run wa padà sí wọ̀bìà, tí wọn sì ń ṣẹ́ Olúwa wa kansoso náà, àní Jésù Kírísítì Olúwa.

5 Nítòótọ́, ẹ ti mọ nǹkan wọ̀nyí ní ẹ̀ẹ̀kan rí, mo fẹ́ rán an yín létí pé, lẹ́yìn tí Olúwa ti gba àwọn kan là láti ilẹ̀ Éjíbítì wá, lẹ́yìn náà ni ó run àwọn tí kò gbàgbọ́.

6 Àti àwọn ańgẹ́lì tí kò tọ́jú ipò ọlá wọn, ṣùgbọ́n tí wọn fi ipò wọn sílẹ̀, àwọn tí ó pamọ́ sínú ẹ̀wọ̀n àìnípẹ̀kun ní ìṣàlẹ̀ òkùnkùn de ìdájọ ọjọ́ ńlá nì.

7 Àní bí Sódómù àti Gomorà, àti àwọn ìlú agbégbé wọn, ti fi ara wọn fún àgbérè ṣíṣe, tí wọ́n sì ń tẹ̀lé ará àjèjì lẹ́yìn, àwọn ni ó fi lélẹ̀ bí àpẹrẹ, àwọn tí ó ń jìyà iná àìnípẹ̀kun.

8 Bákan náà ni àwọn wọ̀nyí ń sọ ara wọn di èérí nínú àlá wọn, wọ́n ń gan ìjoye, wọn sì ń sọ̀rọ̀ búbúrú sí àwọn ọlọ́lá.

9 Ṣùgbọ́n Mákẹ́lì, olórí awọn ańgẹ́lì, nígbà tí ó ń bá Èṣù jiyàn nítórí òkú Mósè, kò sọ ọ̀rọ̀ òdì sí i; Ṣùgbọ́n ó wí pé, “Olúwa bá ọ wí.”