1 Pọ́ọ̀lù, ìránṣẹ́ Ọlọ́run àti Àpósítélì Jésù Kírísítì, gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run, àti ìmọ̀ òtítọ́ irú èyí tí í máa darí ènìyàn sí ìgbé ayé ìwà bí Ọlọ́run—
2 ìgbàgbọ́ àti ìmọ̀ tí ó dúró lórí ìrètí iyè àìnípẹ̀kun, èyí tí Ọlọ́run tí kì í purọ́ ti se ìlérí rẹ̀ ṣáájú kí ayé tó bẹ̀rẹ̀,
3 àti pé ní àkókò tirẹ̀, òun ti fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ hàn nínú ìwàásù tí a fi lé mi lọ́wọ́ nípa àṣẹ Ọlọ́run Olùgbàlà wa.
4 Sí Títù, ọmọ mi tòótọ́ nínú ìgbàgbọ́ wa kan náà.Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run baba àti Kírísítì Jésù Olùgbàlà wa.
5 Ìdí tí mo fi fi ọ́ sílẹ̀ ní Kírétè ni pé kí o lè ṣe àsepé àwọn iṣẹ́ tó sẹ́kù. Mo sì ń rọ̀ ọ́ kí o yan àwọn alàgbà ní ìlú kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí mo ṣe darí rẹ̀.
6 Ẹni tí yóò jẹ́ alàgbà gbọdọ̀ jẹ́ aláìlábùkù, wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ onìyàwó kan, ọmọ wọn náà gbọdọ̀ jẹ́ onígbàgbọ́ tí kò ní ẹ̀sùn ìwà ipá tàbí ẹ̀sùn àìgbọ́ràn kankan.
7 Alámójútó jẹ́ ẹni tí a gbé iṣẹ́ Ọlọ́run lé lọ́wọ́, nítorí náà, kò gbọdọ̀ ní àbùkù kankan tàbí agbéraga, oníjà, kò gbọdọ̀ jẹ́ ọ̀mùtí tàbí alágídí tàbí olójúkòkòrò.