Títù 1:4-10 BMY

4 Sí Títù, ọmọ mi tòótọ́ nínú ìgbàgbọ́ wa kan náà.Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run baba àti Kírísítì Jésù Olùgbàlà wa.

5 Ìdí tí mo fi fi ọ́ sílẹ̀ ní Kírétè ni pé kí o lè ṣe àsepé àwọn iṣẹ́ tó sẹ́kù. Mo sì ń rọ̀ ọ́ kí o yan àwọn alàgbà ní ìlú kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí mo ṣe darí rẹ̀.

6 Ẹni tí yóò jẹ́ alàgbà gbọdọ̀ jẹ́ aláìlábùkù, wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ onìyàwó kan, ọmọ wọn náà gbọdọ̀ jẹ́ onígbàgbọ́ tí kò ní ẹ̀sùn ìwà ipá tàbí ẹ̀sùn àìgbọ́ràn kankan.

7 Alámójútó jẹ́ ẹni tí a gbé iṣẹ́ Ọlọ́run lé lọ́wọ́, nítorí náà, kò gbọdọ̀ ní àbùkù kankan tàbí agbéraga, oníjà, kò gbọdọ̀ jẹ́ ọ̀mùtí tàbí alágídí tàbí olójúkòkòrò.

8 Wọ́n ní láti jẹ́ olùfẹ́ àlejò ṣíṣe, olùfẹ́ ohun tí ó dára. Wọ́n ní láti jẹ́ ẹni tí ó kò ara rẹ̀ ní ìjánu, ẹni dúró sinsin, ọlọ́kàn mímọ́, àti ẹni oníwàtítọ́.

9 Ó gbọdọ̀ di ẹ̀kọ́ nìpa ìdúrósinsin mú dáadáa gẹ́gẹ́ bí ó ti kọ́ọ, kí ó lè fi ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro kọ́ àwọn ẹlòmíràn. Nípa èyí, yóò lè fi ìdí òtítọ́ múlẹ̀ fún àwọn alátakò.

10 Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni ọlọ̀tẹ̀, afínnú àti ẹlẹ́tàn pàápàá jùlọ láàrin àwọn onílà.