12 Ó ń kọ́ wa láti sẹ́ àìwà-bí Ọlọ́run àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ayé, kí a gbé ìgbé ayé ìkóra-ẹni-ní-ìjánu, ìdúrósinsin àti ìwà-bí-Ọlọ́run ní ayé ìsínsìnyìí,
13 bí a ti ń wọ̀nà fún ìrètí tó ní bùkún, èyí ń ní ìfarahàn ògo Ọlọ́run wa tí ó tóbi àti Olùgbàlà wa Jésù Kírísìtì.
14 Ẹni tí ó fi ara rẹ̀ fún wa láti rà fún ìràpàda kúrò nínú ìwà búburú gbogbo àti kí ó sì le wẹ̀ àwọn ènìyàn kan mọ́ fún ara rẹ̀ fún iní ohun tìkara rẹ̀, àwọn tó ń ní ìtara fún iṣẹ́ rere.
15 Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni kí ìwọ kí ó máa kọ wọn. Gba ni níyànjú kí ó sì máa fi gbogbo àṣẹ bániwí. Máe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni kí ó gàn ọ́.