5 láti jẹ́ ẹni ìwọ̀ntúnwọ̀nsì àti ọlọ́kàn mímọ́, kí wọ́n máa ṣe ojúse wọn nínú ilé, wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ onínú rere, kí wón sì máa tẹríba fún àwọn ọkọ wọ́n, kí ẹnikẹ́ni máa baà sọ̀rọ̀ òdì sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
6 Bákan náà, rọ àwọn ọ̀dọ́ ọkùnrin láti kó ara wọn ni ìjánu.
7 Nínú ohun gbogbo fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí alápẹẹrẹ ohun rere. Nínú ẹ̀kọ́ rẹ fi apẹẹrẹ ìwà pípé hàn, ẹni tó kún ojú òsùnwọ̀n
8 jẹ́ ẹni tó jáfáfà nínú ọ̀rọ̀ sísọ, ẹni tí kò see tanù, kí ojú kò lé tí àwọn alátakò rẹ̀ nígbà tí wón kò bá rí ohun búburú sọ nípa rẹ̀.
9 Kọ́ àwọn ẹrú láti se ìgbọ́ran sí àwọn olówó wọn nínú ohun gbogbo, láti máa gbìyànjú láti tẹ́ wọn lọ́rùn, wọn kò gbọdọ̀ gbó olówó wọn lẹ́nu,
10 wọn kò gbọdọ̀ jàwọ́n lólè ohunkóhun, ṣùgbọ́n kí wón jẹ́ ẹni tó seé gbẹ́kẹ̀lé, kí wọn ó làkàkà ní gbogbo ọ̀nà láti jẹ́ kí ìkọ́ni nípa Ọlọ́run àti Olùgbàlà ní ìtumọ̀ rere.
11 Nítorí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tó mú ìgbàlà wà ti fara hàn fún gbogbo ènìyàn.