1 Rán àwọn ènìyàn náà létí láti máa tẹríba fún ìjọba àti àwọn aláṣẹ. Kí wọn ṣe ìgbọ́ràn nígbà gbogbo, kí wọn sì múra fún iṣẹ́ rere gbogbo.
2 Wọn kò gbọdọ̀ sọ̀rọ̀ ẹnikẹ́ni ní ibi, kí wọn jẹ́ ẹni àlááfíà àti ẹni pípé, kí wọn sì máa gbé ìgbé-ayé ìwà tútù pẹ̀lú ènìyàn gbogbo.
3 Nígbà kan rí, àwa pàápàá jẹ́ opè àti aláìgbọ́ràn, àti tàn wá jẹ, a sè ti sọ wá di ẹrú fún onírúurú ìfẹ́kùfẹ̀ẹ́ àti adùn ayé. À ń gbé ìgbé-ayé àrankan àti owú kíkorò, a jẹ́ ẹni ìríra, a sì ń kórira ọmọ ẹnìkejì wa pẹ̀lú.
4 Ṣùgbọ́n nígbà tí inú rere àti ìfẹ́ Ọlọ́run Olùgbàlà wa farahàn,
5 Ó gbà wá là. Kì í ṣe nípa iṣẹ́ tí àwa ṣe nínú òdodo bí kò ṣe nítorí àánú rẹ̀. Ó gbà wá là, nípaṣẹ̀ ìwẹ̀nù àtúnbí àti ìsọdọ̀tun ti Ẹ̀mí Mímọ́,
6 èyí tí tú lé wa lórí ní ẹ̀kún-rẹ́rẹ́ nípaṣẹ̀ Jésù Kírísítì Olùgbàlà wá.
7 Tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí ó jẹ́ wí pé lẹ́hìn tí a tí dáwa láre nípaṣẹ̀ oore-ọ̀fẹ́, kí a lè jẹ́ ajùmọ̀jogún ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun.