1 Adura tí wolii Habakuku kọ lórin nìyí:
2 OLUWA, mo ti gbọ́ òkìkí rẹ,mo sì bẹ̀rù iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.Gbogbo bí ò ó tíí ṣe tí à ń gbọ́;tún wá ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tiwa;sì ranti àánú ní àkókò ibinu rẹ.
3 OLUWA wá láti Temani,Ẹni Mímọ́ sì wá láti òkè Parani.Ògo rẹ̀ bo ojú ọ̀run,gbogbo ayé sì kún fún ìyìn rẹ̀.
4 Dídán rẹ̀ dàbí ọ̀sán gangan,ìtànṣán ń ti ọwọ́ rẹ̀ jáde;níbẹ̀ ni ó fi agbára rẹ̀ pamọ́ sí.
5 Àjàkálẹ̀ àrùn ń lọ níwájú rẹ̀,ìyọnu sì ń tẹ̀lé e lẹ́yìn pẹ́kípẹ́kí.