1 Iṣẹ́ tí OLUWA rán wolii Malaki sí àwọn ọmọ Israẹli nìyí.
2 OLUWA ní, “Mo fẹ́ràn yín pupọ.” Ṣugbọn ẹ̀ ń bèèrè pé, “Kí ló fihàn pé o fẹ́ràn wa?”OLUWA dáhùn pé, “Ṣebí tẹ̀gbọ́n-tàbúrò ni Esau ati Jakọbu?
3 Sibẹ mo fẹ́ràn Jakọbu, mo sì kórìíra Esau. Mo ti sọ gbogbo àwọn ìlú òkè Esau di ahoro, mo sì sọ ilẹ̀ ìní rẹ̀ di ilé ajáko tí ó wà ní aṣálẹ̀.”
4 Bí Edomu bá sọ pé, “Ìlú wa ti di òkítì àlàpà, ṣugbọn a óo tún un kọ́.” Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo wá dáhùn pé, “Wọ́n lè máa kọ́ ọ, ṣugbọn n óo tún máa wó o lulẹ̀ títí tí àwọn eniyan yóo fi máa pè wọ́n ní orílẹ̀-èdè burúkú, àwọn ẹni tí OLUWA bínú sí títí lae.”
5 Ẹ óo fi ojú ara yín rí i ẹ óo sì sọ pé, “OLUWA tóbi lọ́ba, kódà títí dé ilẹ̀ tí kì í ṣe ilẹ̀ Israẹli!”
6 “Ọmọ a máa bọ̀wọ̀ fún baba rẹ̀, iranṣẹ a sì máa bẹ̀rù oluwa rẹ̀. Bí mo bá jẹ́ baba yín, ṣé ẹ̀ ń bọ̀wọ̀ fún mi? Bí mo bá sì jẹ́ oluwa yín, ṣé ẹ bẹ̀rù mi ni èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ń bi ẹ̀yin alufaa tí ẹ̀ ń tàbùkù orúkọ mi? Sibẹsibẹ ẹ̀ ń bèèrè pé, ‘Ọ̀nà wo ni a fi ń tàbùkù orúkọ rẹ?’
7 Ìdí rẹ̀ tí mo fi ní ẹ̀ ń tàbùkù orúkọ mi ni pé, ẹ̀ ń fi oúnjẹ àìmọ́ rúbọ lórí pẹpẹ mi. Ẹ tún bèèrè pé, ‘Ọ̀nà wo ni a fi sọ pẹpẹ rẹ di àìmọ́?’ Ẹ ti tàbùkù pẹpẹ mi, nípa rírò pé ẹ lè tàbùkù rẹ̀.