Malaki 1:8-14 BM

8 Nígbà tí ẹ bá mú ẹran tí ó fọ́jú, tabi ẹran tí ó múkùn-ún, tabi ẹran tí ń ṣàìsàn wá rúbọ sí mi, ǹjẹ́ kò burú? Ṣé ẹ lè fún gomina ní irú rẹ̀ kí inú rẹ̀ dùn si yín, tabi kí ẹ rí ojurere rẹ̀?”

9 Nisinsinyii, ẹ̀yin alufaa, ẹ mú irú ọrẹ bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́, ẹ̀ ń gbadura sí Ọlọrun, pé kí ó lè fi ojurere wò yín; Ṣé ẹ rò pé OLUWA yóo fi ojurere wo ẹnikẹ́ni ninu yín?

10 Ìbá ti dára tó kí ẹnìkan ninu yín ti ìlẹ̀kùn tẹmpili pa, kí ẹ má baà máa wá tanná mọ́, kí ẹ máa rú ẹbọ asán lórí pẹpẹ mi! Inú mi kò dùn si yín, n kò sì ní gba ọrẹ tí ẹ mú wá.

11 Nítorí pé, jákèjádò gbogbo ayé, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ rẹ̀ ni orúkọ mi ti tóbi láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, ibi gbogbo ni wọ́n sì ti ń sun turari sí mi, tí wọ́n sì ń rú ẹbọ mímọ́ sí mi láàrin àwọn orílẹ̀-èdè.

12 Ṣugbọn ẹ tàbùkù orúkọ mi nígbà tí ẹ sọ pé pẹpẹ OLUWA ti di àìmọ́, tí ẹ sì ń fi oúnjẹ tí ẹ pẹ̀gàn rúbọ lórí rẹ̀.

13 Ẹ̀ ń sọ pé, “Èyí sú wa!” Ẹ̀ ń yínmú sí mi. Ẹran tí ẹ fi ipá gbà, tabi èyí tí ó yarọ, tabi èyí tí ń ṣàìsàn ni ẹ̀ ń mú wá láti fi rúbọ. Ṣé ẹ rò pé n óo gba irú ẹbọ bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ yín?

14 Ègún ni fún arẹ́nijẹ; tí ó jẹ́jẹ̀ẹ́ akọ ẹran láti inú agbo rẹ̀, ṣugbọn tí ó fi ẹran tí ó ní àbùkù rúbọ sí OLUWA. Ọba ńlá ni mí, gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ni wọ́n sì bẹ̀rù orúkọ mi.