1 OLUWA ní, “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin alufaa, ẹ̀yin ni àṣẹ yìí wà fún.
2 Bí ẹ kò bá ní gbọ́ràn, tí ẹ kò sì ní fi sọ́kàn láti fi ògo fún orúkọ mi, n óo mú ègún wá sórí yín, ati sórí àwọn ohun ìní yín. Mo tilẹ̀ ti mú ègún wá sórí àwọn ohun ìní yín, nítorí pé ẹ kò fi ọ̀rọ̀ mi sọ́kàn.
3 Ẹ wò ó! N óo jẹ àwọn ọmọ yín níyà, n óo fi ìgbẹ́ ẹran tí ẹ fi ń rúbọ kùn yín lójú, n óo sì le yín kúrò níwájú mi.
4 Nígbà náà ni ẹ óo mọ̀ pé èmi ni mo pàṣẹ yìí fun yín, kí majẹmu mi pẹlu Lefi má baà yẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni èmi, OLUWA àwọn ọmọ ogun wí!
5 “Majẹmu ìyè ati alaafia ni majẹmu mi pẹlu Lefi. Mo bá a dá majẹmu yìí kí ó baà lè bẹ̀rù mi; ó sì bẹ̀rù mi, ó bọ̀wọ̀ fún orúkọ mi.
6 Ó fi ẹ̀kọ́ òtítọ́ kọ́ni, kìí sọ̀rọ̀ àìtọ́. Ó bá mi rìn ní alaafia ati ìdúróṣinṣin, ó sì yí ọkàn ọpọlọpọ eniyan pada kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀.