Malaki 2:10-16 BM

10 Ṣebí baba kan náà ló bí wa? Ṣebí Ọlọrun kan náà ló dá wa? Kí ló dé tí a fi ń ṣe aiṣootọ sí ara wa, tí a sì ń sọ majẹmu àwọn baba wa di aláìmọ́?

11 Àwọn ará Juda jẹ́ alaiṣootọ sí OLUWA, àwọn eniyan ti ṣe ohun ìríra ní Israẹli ati ní Jerusalẹmu. Àwọn ará Juda ti sọ ibi mímọ́ tí OLUWA fẹ́ràn di aláìmọ́; àwọn ọmọkunrin wọn sì ti fẹ́ àjèjì obinrin, ní ìdílé abọ̀rìṣà.

12 Kí OLUWA yọ irú eniyan bẹ́ẹ̀ kúrò ní àwùjọ Jakọbu, kí ó má lè jẹ́rìí tabi kí ó dáhùn sí ohun tíí ṣe ti OLUWA, kí ó má sì lọ́wọ́ ninu ẹbọ rírú sí OLUWA àwọn ọmọ ogun mọ́ lae!

13 Ohun mìíràn tí ẹ tún ń ṣe nìyí. Ẹ̀ ń sọkún, omijé ojú yín ń ṣàn lára pẹpẹ OLUWA, ẹ̀ ń sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, ẹ sì ń ké, nítorí pé OLUWA kò gba ọrẹ tí ẹ mú wá fún un.

14 Ẹ̀ ń bèèrè pé, “Kí ló dé tí kò fi gbà á?” Ìdí rẹ̀ ni pé, OLUWA ni ẹlẹ́rìí majẹmu tí ẹ dá pẹlu aya tí ẹ fẹ́ nígbà èwe yín, tí ẹ sì ṣe aiṣootọ sí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé olùrànlọ́wọ́ yín ni, òun sì ni aya tí ẹ bá dá majẹmu.

15 Ṣebí ara kan náà ati ẹ̀jẹ̀ kan náà ni Ọlọrun ṣe ìwọ pẹlu rẹ̀? Kí ló dé tí Ọlọrun fi ṣe bẹ́ẹ̀? Ìdí rẹ̀ ni pé, Ọlọrun ń fẹ́ irú ọmọ tí yóo jẹ́ tirẹ̀. Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra yín, kí ẹ má ṣe hùwà aiṣootọ sí aya tí ẹ fẹ́ nígbà èwe yín.

16 “Mo kórìíra ìkọ̀sílẹ̀ láàrin tọkọtaya, mo kórìíra irú ìwà ìkà bẹ́ẹ̀ sí olólùfẹ́ ẹni. Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra, kí ẹ má ṣe jẹ́ alaiṣootọ sí aya yín. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun wí!”