Malaki 3:10-16 BM

10 Ẹ mú gbogbo ìdámẹ́wàá yín wá sí ilé ìṣúra, kí oúnjẹ baà lè wà ninu ilé mi. Ẹ ṣe bẹ́ẹ̀ kí ẹ fi dán mi wò, bí n kò bá ní ṣí fèrèsé ọ̀run sílẹ̀, kí n sì tú ibukun jáde fun yín lọpọlọpọ, tóbẹ́ẹ̀ tí kò ní sí ààyè tó láti gbà á.

11 N kò ní jẹ́ kí kòkòrò ajẹnirun jẹ ohun ọ̀gbìn yín lóko, ọgbà àjàrà yín yóo sì so jìnwìnnì.

12 Nígbà náà ni àwọn orílẹ̀-èdè yóo máa pè yín ní ẹni ibukun, ilẹ̀ yín yóo sì jẹ́ ilẹ̀ ayọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun wí!”

13 OLUWA ní, “Ẹ ti fi ẹnu yín sọ ọ̀rọ̀ burúkú sí mi. Sibẹsibẹ ẹ̀ ń wí pé, ‘Irú ọ̀rọ̀ burúkú wo ni a sọ sí ọ?’

14 Ẹ sọ pé, ‘Kí eniyan máa sin Ọlọrun kò jámọ́ nǹkankan. Kò sì sí èrè ninu pípa òfin rẹ̀ mọ́ tabi ninu rírẹ ara wa sílẹ̀ níwájú OLUWA àwọn ọmọ ogun.

15 Ohun tí ń ṣẹlẹ̀ nisinsinyii ni pé: ó ń dára fún àwọn agbéraga; kì í sì í ṣe pé ó ń dára fún àwọn eniyan burúkú nìkan, ṣugbọn nígbà tí wọ́n bá fi ìwà burúkú wọn dán Ọlọrun wò, kò sí nǹkankan tí ń ṣẹlẹ̀ sí wọn.’ ”

16 Nígbà tí àwọn tí wọ́n bẹ̀rù OLUWA bá ń bá ara wọn sọ̀rọ̀, OLUWA a máa tẹ́tí sí wọn, yóo sì gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn. Ó ní ìwé kan níwájú rẹ̀ ninu èyí tí àkọsílẹ̀ àwọn tí wọ́n bẹ̀rù OLUWA, tí wọ́n sì ń bọ̀wọ̀ fún orúkọ rẹ̀ wà.