Mika 1:1-7 BM

1 Ọ̀rọ̀ tí OLUWA sọ fún Mika, ará Moreṣeti nípa Jerusalẹmu ati Samaria nìyí, ní àkókò ìjọba Jotamu, ati ti Ahasi ati ti Hesekaya, àwọn ọba Juda.

2 Ẹ gbọ́, gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè,fetí sílẹ̀, ìwọ ayé, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀.Kí OLUWA fúnrarẹ̀ jẹ́ ẹlẹ́rìí tí yóo takò yín,àní OLUWA, láti inú tẹmpili rẹ̀ mímọ́.

3 Wò ó, OLUWA ń jáde bọ̀ láti inú ilé rẹ̀,yóo sọ̀kalẹ̀, yóo sì rìn lórí àwọn òkè gíga ayé.

4 Àwọn òkè ńlá yóo yọ́ lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀, bí ìda tíí yọ̀ níwájú iná;àwọn àfonífojì yóo pínyàgẹ́gẹ́ bí omi tí a dà sílẹ̀ ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè.

5 Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ Jakọbu, ati ti ilé Israẹli ni gbogbo nǹkan wọnyi yóo ṣe ṣẹlẹ̀. Kí ló fa ẹ̀ṣẹ̀ Jakọbu? Ṣebí ìlú Samaria ni. Kí sì ni ẹ̀ṣẹ̀ ilé Juda? Ṣebí ìlú Jerusalẹmu ni.

6 OLUWA ní, “Nítorí náà, n óo sọ Samaria di àlàpà ní ilẹ̀ tí ó tẹ́jú, yóo di ọgbà ìgbin àjàrà sí; gbogbo òkúta tí a fi kọ́ ọ ni n óo fọ́nká, sinu àfonífojì, ìpìlẹ̀ rẹ̀ yóo sì hàn síta.

7 Gbogbo ère oriṣa rẹ̀ ni a óo fọ́ túútúú, a óo sì jó gbogbo owó iṣẹ́ àgbèrè rẹ̀ níná. Gbogbo ère rẹ̀ ni n óo kójọ bí òkítì, a óo sì kọ̀ wọ́n tì; nítorí pé owó àgbèrè ni ó fi kó wọn jọ, ọrọ̀ rẹ̀ yóo pada sí ọ̀dọ̀ àwọn tí ń bá a ṣe àgbèrè.