Mika 4:2-8 BM

2 Ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè yóo wá, wọn yóo sì wí pé,“Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á lọ sórí òkè OLUWA,ẹ jẹ́ kí á lọ sí ilé Ọlọrun Jakọbu,kí ó lè kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀,kí á sì lè máa tọ̀ ọ́.”Nítorí pé láti Sioni ni òfin yóo ti máa jáde,ọ̀rọ̀ OLUWA yóo sì máa jáde láti Jerusalẹmu.

3 Yóo ṣe ìdájọ́ láàrin ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè,ati láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí ó lágbára ní ọ̀nà jíjìn réré;wọn yóo fi idà wọn rọ ọkọ́,wọn yóo sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ dòjé;àwọn orílẹ̀-èdè kò ní yọ idà sí ara wọn mọ́,wọn kò sì ní kọ́ ogun jíjà mọ́.

4 Ṣugbọn olukuluku yóo jókòó lábẹ́ àjàrà rẹ̀,ati lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, kò sì ní sí ẹni tí yóo dẹ́rùbà wọ́n;nítorí pé OLUWA àwọn ọmọ ogun ni ó sọ bẹ́ẹ̀.

5 Olukuluku orílẹ̀-èdè a máa rìn ní ọ̀nà tí oriṣa rẹ̀ là sílẹ̀, ṣugbọn ọ̀nà OLUWA tí Ọlọrun wa là sílẹ̀ ni àwa yóo máa tọ̀ títí laelae.

6 OLUWA ní, “Nígbà tí ó bá yá, n óo kó gbogbo àwọn arọ jọ, n óo kó àwọn tí mo ti túká jọ, ati àwọn tí mo ti pọ́n lójú.

7 N óo dá àwọn arọ sí, kí wọ́n lè wà lára àwọn eniyan Israẹli tí wọ́n ṣẹ́kù, àwọn tí a túká yóo sì di orílẹ̀-èdè ńlá; OLUWA yóo sì jọba lórí wọn ní òkè Sioni láti ìsinsìnyìí lọ ati títí laelae.”

8 Jerusalẹmu, ìwọ ilé ìṣọ́ agbo aguntan Sioni, ilé ọba rẹ àtijọ́ yóo pada sọ́dọ̀ rẹ, a óo dá ìjọba pada sí Jerusalẹmu.