5 Alaafia yóo sì wà, òun gan-an yóo sì jẹ́ ẹni alaafia.Nígbà tí àwọn ará Asiria bá wá gbógun tì wá, tí wọ́n bá sì wọ inú ilẹ̀ wa, a óo rán àwọn olórí wa ati àwọn akikanju láàrin wa láti bá wọn jà.
6 Idà ni wọn yóo fi máa ṣe àkóso ilẹ̀ Asiria ati ilẹ̀ Nimrodu; wọn yóo sì gbà wá lọ́wọ́ àwọn ará Asiria, nígbà tí wọ́n bá wọ inú ilẹ̀ wa tí wọ́n sì gbógun tì wá.
7 Àwọn ọmọ Israẹli yòókù yóo wà láàrin ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè, bí ìrì láti ọ̀dọ̀ OLUWA wá, ati bí ọ̀wààrà òjò lára koríko, tí kò ti ọwọ́ eniyan wá.
8 Àwọn ọmọ Israẹli yòókù yóo wà láàrin àwọn orílẹ̀-èdè ati ọ̀pọ̀ eniyan, bíi kinniun láàrin àwọn ẹranko igbó, bíi ọ̀dọ́ kinniun láàrin agbo-aguntan, tí ó jẹ́ pé bí ọwọ́ rẹ̀ bá tẹ ẹran, yóo fà á ya, kò sì ní sí ẹni tí yóo lè gbà á lọ́wọ́ rẹ̀.
9 O óo lágbára ju àwọn ọ̀tá rẹ lọ, a óo sì pa wọ́n run.
10 Ní ọjọ́ náà, n óo pa àwọn ẹṣin yín run, n óo sì run gbogbo kẹ̀kẹ́ ogun yín.
11 N óo pa àwọn ìlú tí wọ́n wà lórí ilẹ̀ yín run, n óo sì wó ibi ààbò yín lulẹ̀.