1 Ní gbolohun kan, ẹ̀yin ará mi, ẹ máa yọ̀ ninu Oluwa. Kò ṣòro fún mi láti kọ àwọn nǹkankan náà si yín, ó tilẹ̀ dára bẹ́ẹ̀ fun yín.
2 Ẹ ṣọ́ra fún àwọn ajá. Ẹ ṣọ́ra fún àwọn oníṣẹ́ burúkú. Ẹ ṣọ́ra fún àwọn ọ̀kọlà!
3 Nítorí àwa gan-an ni ọ̀kọlà, àwa tí à ń sin Ọlọrun nípa Ẹ̀mí, tí à ń ṣògo ninu Kristi Jesu, tí a kò gbára lé nǹkan ti ara,
4 bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti gbára lé nǹkan ti ara nígbà kan rí. Bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun ní ìdí láti fi gbára lé nǹkan ti ara, mo ní i ju ẹnikẹ́ni lọ.
5 Ní ọjọ́ kẹjọ ni wọ́n kọ mí nílà. Ọmọ Israẹli ni mí, láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini, Heberu paraku ni mí. Nípa ti Òfin Mose, Farisi ni mí.
6 Ní ti ìtara ninu ẹ̀sìn, mo ṣe inúnibíni sí ìjọ Kristi. Ní ti òdodo nípa iṣẹ́ Òfin, n kò kùnà níbìkan.