1 Níbo ni ogun ti ń wá? Níbo ni ìjà sì ti ń wá sáàrin yín? Ṣebí nípa ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ yín tí ó ń jagun ninu àwọn ẹ̀yà ara yín ni.
2 Ẹ̀ ń fẹ́ nǹkankan, ọwọ́ yín kò sì tẹ̀ ẹ́; ẹ bá ń tìtorí rẹ̀ paniyan; ẹ̀ ń jowú nítorí nǹkankan, ọwọ́ yín kò bá ohun tí ẹ̀ ń jowú lé lórí, ẹ bá sọ ọ́ di ọ̀ràn ìjà ati ogun. Ọwọ́ yín kò tẹ ohun tí ẹ fẹ́ nítorí pé ẹ kò bèèrè lọ́dọ̀ Ọlọrun.
3 Bí ẹ bá sì bèèrè, ẹ kò rí ohun tí ẹ bèèrè gbà nítorí èrò burúkú ni ẹ fi bèèrè, kí ẹ lè lo ohun tí ẹ bèèrè fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara yín.
4 Ẹ̀yin àgbèrè, ẹ kò mọ̀ pé ìbá ayé ṣọ̀rẹ́ níláti jẹ́ ìbá Ọlọrun ṣọ̀tá? Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ ayé ti yàn láti jẹ́ ọ̀tá Ọlọrun.
5 Àbí ẹ rò pé lásán ni Ìwé Mímọ́ sọ pé, “Ẹ̀mí tí ó fi sinu wa ń jowú gidigidi lórí wa?”